By Adeṣọla Adunni
Titi di asiko yii, igbimọ to jokoo lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ko ti i fi abọ wọn jẹ fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu. Ohun to fa a ni pe awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ peju sibi ipade apero awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ lagbaaye, eyi ti wọn n ṣe ni Geneva, lorileede Switzerland. Igbimọ yii ni akọwe ijọba apapọ, Sẹnetọ George Akume, yoo ṣiwaju wọn lọọ jabọ fun Aarẹ Tinubu.
Read Also: Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ: Àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ẹ́ gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹta, oṣu yii ni ipade apero ẹgbẹ oṣiṣẹ lagbaaye bẹrẹ, yoo si pari lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Abọ ti wọn ba jẹ fun Tinubu yii ni yoo ṣi ọna owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ ilẹ wa.
Inu oṣu kinni, ọdun yii ni ijọba apapọ gbe igbimọ ti Bukar Goni Aji lewaju rẹ kalẹ lori ọrọ owo oṣu tuntun, ti wọn si jabọ fun aarẹ lanaa. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni igbimọ ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, awọn aṣoju lẹka ileeṣẹ aladaani atawọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ wa, pari ijiroro lori ọrọ naa. Ẹgbẹrun lọna mejilelgọta ni igbimọ yii dabaa, ti ẹgbẹ oṣiṣẹ si dabaa ẹgbẹrun lọna igba o le ni aadọta, eyi ti aṣoju awọn gomina nibi igbimọ yii, Hope Uzodinma, ti ipinlẹ Imo, ni awọn gomina o le san ẹgbẹrun mejilalọgọta ti igbimọ ijọba apapọ dabaa rẹ yii.
