Tag: Àṣíírí

  • Àṣíírí tú!

    Àṣíírí tú!

    Àwọn àáfà mẹ́ta hú òkú ọmọ ọdún kan
    Wọ́n gé orí àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, òògùn owó ni wọ́n fẹ́ẹ́ fi ṣe
    BY Kayọde Ọmọtọṣọ

    Pẹlu bi iku Taiwo Bisiriyu, ọmọ ọdun kan to ku nifọnna-fọnṣu ni adugbo Omi-Ifọn, nijọba ibilẹ Odigbo, nipinlẹ Ondo, ṣe jẹ ibanujẹ nla fawọn obi rẹ, iwa ọdaju lawọn ọbayejẹ mẹta kan tun hu pẹlu bi wọn ṣe lọọ hu oku ọmọ ọhun ti wọn si tun yọ awọn ẹya ara rẹ, wọn ni awọn fẹẹ fi ṣe oogun owo.

    Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ. Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ karun-un, oṣu yii ni Taiwo ku, ọjọ naa ni awọn obi rẹ ranṣẹ pe awọn aafa mẹta kan, Aliyu Musa, Aliyu Taiye, ati Wasiu Babatunde, pe ki wọn waa ba awọn kirun si i lara ki awọn too sin in. Ṣugbọn ṣa, lẹyin ti wọn sinku ọmọ ọhun tan ni wọn pada lọọ hu oku rẹ.

    Awọn olugbe adugbo Omi-Ifọn ṣalaye pe lara awọn nnkan ti wọn ba nile awọn afaa yii ni ọmọ odo, odo nla kan, asejẹ atawọn nnkan mi-in to mu ifura lọwọ. Nigba ti iya Taiwo, Risikat Bisiriyu, n sọrọ, o ni “ara ọmọ mi ni ko ya ti mo gbe e lọ si ọsibitu Maternity Center fun itọju. Lẹyin eyi ni wọn ni ki n maa gbe e lọ si ọsibitu Jẹnẹra, niluu Ọrẹ, ṣugbọn bi a ṣe debẹ lọmọ ọhun dakẹ. Mo sun ẹkun kikoro, eyi lo si jẹ ki awọn ara adugbo mọ. Bi a ṣe dele ni a ni ka sinku rẹ nitori ẹlẹsin Musulumi ni wa, a si ranṣẹ pe awọn aafa. Lọjọ naa ni ọkan ninu awọn aafa yii wọ inu igbo aginju kan lọ, o ni ibẹ lawọn fẹẹ sinku rẹ si,  ṣugbọn aburo baba ọmọ yii ni ki wọn sin in si itosi, ko ma jẹ inu aginju.

    “Ọjọ Ẹti, Furaidee, lọmọ ọhun ku. Aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ti a jokoo sita ile wa ni iyawo ọkan ninu awọn aafa yii de to sọ fun wa pe oun o mọ ohun ti ọkọ oun gbe wale to n run, ṣugbọn a ko ka ọrọ to sọ si rara.

    Nnkan bii aago mọkanla oru ọjọ Aje ọhun ni a bẹrẹ si i gbọ ti afaa yii n gun nnkan ninu odo, o si gun un di aago mẹrin aabọ idaji ọjọ keji. Pẹlu awada ni mo fi sọ pe Ọlọrun lo mọ ohun to n gun ọhun ti ko jẹ ka ri oorun sun.

    “Ọjọ keji lẹyin ti mo dari de lati ọja ni iyawo aafa yii tun waa ba mi pe ara fu oun pe oku Taiwo ni ọkọ oun n gun ninu odo ṣugbọn mo sọ fun un ko gbẹnu rẹ dakẹ. Mo waa sọ fun aburo baba Taiwo, oun naa si sọ pe oun gbọ, bi a ṣe bẹrẹ si i fura niyẹn. A lọ si ibi ti wọn sinku ọmọ ọhun si, a si ri i pe wọn ti hu u. Nigba ti Imaamu adugbo ọhun gbọ, o fun wa laṣẹ lati hu oku yii jade, lẹyin ti a hu u tan ni a ri i pe wọn ti ge ori ati ọwọ ọmọ ọhun lọ.”

    Akọroyin wa gbọ pe teṣan ọlọpaa Odigbo, nipinlẹ Ondo ni wọn fi iroyin iṣẹlẹ yii to leti, lẹsẹkẹsẹ ni awọn ọlọpaa si gbe awọn afurasi yii. Awọn ọlọpaa wọ awọn afurasi ọdaran naa lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Odigbo, ẹsun hihuwa ti ko boju mu ni wọn fi kan wọn niwaju adajọ. Agbefọba to n rojọ tako wọn, James Usifo, ni pe ọjọ karun-un ati ọjọ kẹsan-an, oṣu yii ni awọn olujẹjọ naa huwa yii ni adugbo Alagbado, Omifọn, lọna Odigbo, nipinlẹ Ondo. O ni ṣe ni wọn hu oku Taiwo Bisiriyu, ti wọn si ge ori ati ọwọ rẹ lọ. O ni ṣe ni wọn tun ba awọn oogun abẹnugọngọ lọwọ wọn, eyi to tako ofin ti ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006. Usifo ni ki adajọ fun oun laaye lati ko awọn ẹlẹrii wa jẹrii tako awọn olujẹjọ ọhun nile-ẹjọ. Agbẹjọro awọn olujẹjọ, H.A Ogiren, ko tako ẹbẹ agbẹjọro ijọba yii, o ni ṣugbọn ki adajọ fun awọn onibaara oun ni beeli.

    Ṣa, Adajọ Festus Akinlolu ti sun idajọ lori ọrọ beeli awọn afurasi ọdaran yii si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to n bọ.