Tag: Àrùn Kọ́lẹ́rà

  • Àrùn Kọ́lẹ́rà tàn dé ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́ta ló ti pa

    Àrùn Kọ́lẹ́rà tàn dé ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́ta ló ti pa

    By Kayọde Ọmọtọṣọ

    Ko din ni eeyan mẹtalelọgọta ti arun onigbameji, tọpọ eeyan tun mọ si Kọlẹra, ti pa ni awọn ipinlẹ mẹtalelọgbọn lorileede yii. Ajọ to n mojuto arun pajawiri nilẹ yii (NCDC), lo sọ eyi di mimọ lanaa. Awọn ipinlẹ ti arun yii ti gbilẹ ju ni Eko, Bayelsa, Zamfara, Abia, Cross River, Bauchi, Delta, Katsina, Imo, ati Nasarawa.

    Tẹ o ba gbagbe, ọjọ ti pẹ diẹ ti ijọba apapọ ti n pariwo nipa arun yii.

    Read Also: Ìbẹ̀rù-bojo gbọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn òṣìṣẹ́ fásitì fẹ́ẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀

        Arun kọlẹra jẹ arun kan ti eeyan maa n ko latara ounjẹ jijẹ tabi omi mimu. Ajọ NCDC ni ọna kan ti eeyan le fi dena arun yii ni ki eeyan ri i daju pe agbegbe rẹ wa ni mimọ toni-toni, ki eeyan mu omi to mọ geere, ki eeyan da ilẹ nu sibi to yẹ, ki a si maa fi omi pẹlu ọṣẹ fọ ọwọ wa ni gbogbo igba. Ajọ yii kilọ fawọn eeyan lati yẹra fun awọn ounjẹ pẹlu eso ti wọn n kiri nigboro, bẹẹ si ni ki wọn maa se awọn ẹran tabi ẹja wọn daadaa.Wọn tun gba awọn eeyan nimọran lati maa bọ omi ti wọn ba fẹẹ mu, ki wọn si bo ibi ti wọn ba gbe e si, ki arun ọhun ma ba a tan kalẹ.

    Latari bi arun yii ṣe n tan kalẹ ni ijọba ipinlẹ Eko fi figbe ta lọsẹ to kọja, ti wọn si kilọ fun awọn olugbe ilu ọhun pe ki wọn ṣọra fun arun onigba meji to lu igboro pa yii. Gẹgẹ bi ipinlẹ ọhun ṣe ṣalaye ninu atẹjade ti wọn fi sita, wọn ni eeyan marun-un lo ti ku latari itankalẹ arun yii laarin wakati mejidinlaadọta.

    Kọmisanna feto ilera nipinlẹ Eko, Dokita Akin Abayọmi, ṣalaye pe awọn ijọba  ibilẹ tawọn ti ṣakiyesi pe arun yii gbilẹ ju ni Eti-Ọsa, Isalẹ Eko, Ikorodu, ati Koṣọfẹ.

    Abayọmi ni ko din ni ọgọta eeyan ti wọn n gbatọju lọwọ nileewosan kaakiri ipinlẹ Eko fun arun yii, atipe ọpọ wọn lo n ṣe igbọnsẹ gbuuru, ti wọn si tun n bi pẹlu. O ni latari ojo arọda to n rọ lọwọ nipinlẹ Eko, oriṣiiriṣii arun lo n tan kaakiri ipinlẹ naa, eyi to fa a ti awọn ileewosan fi n kun akunfaya. Abayọmi ni “a ti ta awọn oṣiṣẹ ilera wa lolobo lati maa finmu finlẹ fun awọn ohun to le fa a. A ti ni ki wọn ṣewadii omi ti idọti wa ninu rẹ kan to n ṣan kaakiri lati agbegbe Lẹkki, mọ Victoria Island.”

    O ṣalaye pe lara ami to maa n wa lara ẹni ti arun yii ba n ṣe ni onitọhun yoo maa yagbẹ gbuuru, yoo maa bi, omi yoo maa gbẹ lara rẹ, iba yoo ṣe e, ti o si tun le daku nigba mi-in.

         Gẹgẹ bo ṣe sọ, lara itọju fun arun yii ni lilo omi kan ti wọn n pe ni Oral Rehydration Salts (ORS), eyi ti yoo da omi ti onitọhun ba padanu pada si agọ ara rẹ. O rọ awọn eeyan lati maa bọ omi ti wọn ba fẹẹ mu daadaa, ki wọn fọ ọwọ wọn pẹlu omi ati ọṣẹ ni gbogbo igba ti wọn ba lọ ile igbọnsẹ tabi ti wọn ba fẹẹ dana ounjẹ. O ni ki kaluku tete maa fi irufẹ iṣẹlẹ yii to ajọ NCDC tabi ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Eko leti ti wọn ba ṣakiyesi rẹ lagbegbe wọn.

    Bakan naa, ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọhun-un ni ijọba ipinlẹ Ọyọ figbe ta pe arun kọlẹra yii ti wọ ipinlẹ ọhun wa. Kọmisanna feto ilera nipinlẹ ọhun, Dokita Oluwaṣẹrimi Ajetunmọbi, lasiko to ṣabẹwo si ileewosan aladaani kan ti awọn meji ti wọn furasi pe wọn ni arun yii ti n gbatọju niluu Ibadan,sọ pe ibi ounjẹ tabi ohun mimu ni eeyan le ti ko arun ọhun. Kọmisanna ni pe awọn meji to ni arun yii ni akiyesi wa pe lati ilu Lẹkki, nipinlẹ Eko, ni awọn eeyan meji yii ti wa, atipe oṣiṣẹ nibi ti wọn ti n kọle ni wọn. Ajetunmọbi ni pe lọwọlọwọ bayii, awọn ti bẹrẹ ipolongo lori redio, tẹifisan ati ni ikanni ayelujara kaakiri lati fi ta awọn eeyan lolobo lori ọna ti wọn le gba lati fi dena arun yii. O ni ẹnikẹni to ba ṣakiyesi awọn ami arun yii ko ma wulẹ jokoo sile, ko tete lọọ gbatọju nileewosan to ba wa nitosi wọn.