By Adeṣọla Adunni
Agbarijọ awọn gomina ilẹ Yoruba ti pinnu lati wa ojutuu si iṣoro ọwọngogo ounjẹ to gbode kan pẹlu bi wọn ṣe pinnu lati bẹrẹ si i pese ounjẹ lẹkun Iwọ-oorun ilẹ wa lọpọ yanturu. Nibi ipade ti awọn gomina yii ṣe niluu Eko lanaa, ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn ti paṣẹ fun awọn kọmisanna eto ọgbin kaakiri ipinlẹ ilẹ Yoruba lati tete gbe igbesẹ lori ọna ti wọn yoo gba maa pese ounjẹ nilẹ Yoruba.
Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ẹni to gba awọn gomina yooku lalejo ṣe sọ, o ni “a mọ riri ipa ti ijọba apapọ n sa lori ipese ounjẹ lọpọ yanturu, a si ti pinnu pe ki gbogbo awọn kọmisanna to n ri si eto ọgbin kaakiri awọn ipinlẹ wa nilẹ Yoruba lati bẹrẹ si i ṣepade pọ, ki wọn si wa ọna ti gbogbo ipinlẹ yoo fi ṣiṣẹ pọ lati pese ounjẹ fun ilẹ Yoruba.”
Read Also: Owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù: Wọn kò tí ì jábọ́ fún Tinubu
Awọn gomina yii ko ṣai waa gboṣuba fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun bo ṣe n ṣatunṣe awọn oju ọna kaakiri nilẹ wa, ti wọn si rọ ọ pe ko ma fi iṣẹ ọhun falẹ rara. Lara awọn oju ọna ti wọn tọka si pe o ti bajẹ lẹkun naa ni ọna to ti Sango-Ọta, nipinlẹ Eko lọ si Abẹokuta, ọna Ibadan si ilu Ileṣa, Akurẹ si Ado-Ekiti, Ibadan si ilu Ọyọ de Ogbomọṣọ lọ si ilu Ilọrin.
Nibi ipade yii ni gbogbo awọn gomina, to fi mọ Babajide Sanwo-Olu ti Eko, Ṣeyi Makinde ti Ọyọ, Dapọ Abiọdun ti Ogun, Lucky Aiyedatiwa ti ipinlẹ Ondo, Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ati Biọdun Oyebanji ti Ekiti peju si. Ṣe ni wọn yan Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko gẹgẹ bi ẹni ti yoo jẹ alaga igbimọ yii lati rọpo Rotimi Akeredolu, gomina ipinlẹ Obdo to dagbere faye, to di ipo ọhun mu tẹlẹ.
