Tag: òṣìṣẹ́ fásitì

  • Ìbẹ̀rù-bojo gbọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn òṣìṣẹ́ fásitì fẹ́ẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀

    Ìbẹ̀rù-bojo gbọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn òṣìṣẹ́ fásitì fẹ́ẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀

    By Kayọde Ọmọtọṣọ

    Ọla  ni gbogbo nnkan yoo bẹrẹ si i da paroaro ni awọn ileewe giga, iyẹn yunifasiti kaakiri orileede yii pẹlu bi ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ lọgba fasiti kaakiri, iyẹn SSANU, ti pinnu lati bẹrẹ iyanṣẹlodi. Ohun ti wọn n beere lọwọ ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ni pe ko sanwo oṣu mẹrin to jẹ awọn tẹlẹ, ko si bẹrẹ si i san ẹgbẹrun lọna marundinlogoji afikun owo oṣiṣẹ to kede rẹ loṣu kẹwaa, ọdun to kọja.

    Ibi ipade alagbara kan ti ẹgbẹ SSANU ṣe ni ilu Benin, nipinlẹ Edo, lọjọ kẹtadinlọgbọn ati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu to kọja ni wọn ti ṣe ipinnu yii. Koda, logunjọ, oṣu to kọja ni ẹgbẹ ọhun ti fi lẹta ṣọwọ si Ọjọgbọn Tahir Mamman, to jẹ minisita feto ẹkọ nilẹ wa eyi ti wọn fi n sọ fun un silẹ pe ko gbaradi fun iyanṣẹlodi tawọn yoo gunle yii, ọla, Ọjọbọ, Tọsidee, ni gbedeke ti wọn fun un yii yoo si tẹnubodo.

    Read Also: Àrùn Kọ́lẹ́rà tàn dé ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́ta ló ti pa

        Atẹjade ti ẹgbẹ SSANU fi sita lanaa ni wọn ti ni ṣe lo da bii igba ti ijọba apapọ n mu awọn ṣere lori adehun to ṣe pẹlu awọn lọdun 2009. Wọn ni pẹlu gbogbo ileri ti Ọjọgbọn Mamman, awọn aṣofin lorileede yii pẹlu minisita fọrọ ẹgbẹ oṣiṣẹ, Nkiruka Onyejeocha, ṣe fawọn pe ijọba yoo san awọn gbese owo oṣu ti wọn jẹ awọn, ṣe lo da bii pe ijọba kan n mu awọn ṣere lori ọrọ yii. Ẹgbẹ ọhun ko ṣai kilọ fun ijọba apapọ lati tete gbe igbesẹ lori ọrọ owo oṣu tuntun ti awọn oṣiṣẹ n beere fuj, bi bẹẹ kọ, awọn yoo da gbogbo nnkan ru lẹka eto ẹkọ ilẹ wa. Wọn waa gboṣuba fun Aarẹ Tinubu fun bo ṣe gbe igbimọ iṣakoso awọn ileewe giga kalẹ, ṣugbọn wọn ni inu awọn o dun si bi ko ṣe yan awọn to nimọ nipa eto ẹkọ si igbimọ naa rara.

    Ṣa, ọkan ọpọlọpọ awọn akẹkọọ ni ko balẹ mọ bayii pẹlu ihalẹ ẹgbẹ SSANU yii, wọn lawọn o mọ ibi tọrọ ọhun yoo yọri si.