Tag: Wale Ẹdun

  • Ẹdun bẹ àwọn iléeṣẹ́ nlánlá: Ilẹ̀ Nàíjíríà rọrùn fún okòòwò yin

    Ẹdun bẹ àwọn iléeṣẹ́ nlánlá: Ilẹ̀ Nàíjíríà rọrùn fún okòòwò yin

    By Adeṣọla Adunni

    Minisita fetoiṣuna nilẹ wa, Wale Ẹdun, ti fọkan awọn ileeṣẹ nlanla balẹ pe orileede Naijiria rọrun fun wọn lati ṣe okoowo wọn, ti wọn yoo si jere rẹpẹtẹ nidii rẹ. Ẹdun sọrọ yii lasiko abẹwo ti awọn aṣoju ileeṣẹ Microsoft ṣe si i niluu Abuja, lanaa, ọjọ Aje, Mọnde. Ileeṣẹ ọhun ti ọga wọn nilẹ Naijiria, Ọlatọmiwa Williams, lewaju wọn, ni ipade yii wa lati ba a le fi idi ibaṣepọ to wa laarin ilẹ Naijiria pẹlu ileeṣẹ ọhun mulẹ si i, ki idagbasoke ba a le ba ẹka ọrọ aje orileede yii.

    Read Also: Owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù: Wọn kò tí ì jábọ́ fún Tinubu

    Ẹdun ni “inu wa dun fun bi ileeṣẹ Microsoft ṣe fi erongba wọn han lati fọeọsowọpọ pẹlu wa lori idaabo bo ẹka ikanni ayelujara, iyẹn ‘cybersecurity’, pẹlu idagbasoke awọn ọdọ eyi ti o ṣe pataki fun idagbasoke ọrọ aje wa.”

    Nigba ti Williams n sọrọ, o ni awọn pinnu lati waa fi ero ọkan awọn han si idagbasoke ilẹ Naijiria, atipe awọn fẹẹ waa tako ahesọ iroyin to n lọ pe awọn fẹẹ fi ilẹ Naijiria silẹ. O ni “a ni gbagbọ ninu ilẹ Naijiria, a si ti pinnu lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lẹka eto aabo ikanni ayelujara. Eyi ṣe pataki fun idagbasoke ati ilọsiwaju awọn ọdọ nilẹ wa.”

  • Wálé Ẹdun fọkàn àwọn ọmọ Nàíjíríà balẹ̀, ó ní: Ètò ọrọ̀ ajé wa ti n gbèrú sí i

    Wálé Ẹdun fọkàn àwọn ọmọ Nàíjíríà balẹ̀, ó ní: Ètò ọrọ̀ ajé wa ti n gbèrú sí i

    By Kayọde Ọmọtọṣọ

    Minisita feto ọrọ aje ilẹ wa, Wale Ẹdun, ti ni eto ọrọ aje ilẹ wa ti ni idagbasoke ti de ba eto ọrọ aje ilẹ wa pẹlu ida mẹta ni abala akọkọ ọdun yii. Ẹdun sọrọ yii niluu Abuja lasiko to n jiṣẹ iriju rẹ fun awọn ọmọ ilẹ Naijiria latigba to ti depo lọdun kan sẹyin. O ni idagbasoke to de ba eto ọrọ aje yii ko ṣẹyin awọn igbesẹ rere ti Aarẹ Tinubu gbe latigba to ti de ori ipo.

    Minisita ọhun ni ipa ti eto ọgbin ko ninu idagbasoke eto ọrọ aje ilẹ wa ko ṣe e fọwọrọ sẹyin, ati pe ida meji o din diẹ ni ẹka eto iṣẹ ọgbin ko ninu ilọsiwaju eto ọrọ aje orileede yii. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ẹka eto ohun ọgbin ṣe pataki nitori phun ni yoo jẹ ọpakutẹlẹ ti ijọba yoo fi koju ọwọngogo ọja lorileede yii, atipe ojuṣe ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ ni lati mu idagbasoke ba igbaye-gbadun awọn ọmọ Naijiria.

    Read Also: BREAKING: Nigeria’s economy growing, says Wale Edun

    Ẹdun, ẹni to jẹ alaga igbimọ to n pin owo ijọbafawọn to ku diẹ kaato fun lawujọ ni eto owo pinpin yii ti bẹrẹ pada ati pe ko din ni miliọnu lọna marunlelaadọrin ọmọ ilẹ Naijiria ti yoo jẹ anfaani owo ọhun. O ni lọna ati ko akoyawọ lori igbesẹ yii, awọn yoo ṣe e ni ifọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ to n ri sọrọ ibaraẹnisọrọ ati ti awọn  ọdọ, ki owo ọhun ba a le e de ọdọ awọn to yẹ.