Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀ lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbọn tí wọ́n fẹ́ẹ́ kó wọlé lẹ́nu ibodè

*Afurasí mẹ́ta ti wà láhàámọ́

By Kayọde Ọmọtọṣọ

Ajọ to n mojuto ofin to de ohun ija oloro iyẹn National Centre for the Control of Small Arms and Light Weapons (NCCSALW), ti gba iṣakoso awọn ohun ija ti ajọ aṣọbode ilẹ wa gba lẹnu ibode. Adari ajọ naa, Johnson Babatunde Kokumọ, gboṣuba fun ajọ aṣọbode fun bi wọn ṣe ri ọpọlọpọ ohun ija yii gba pada, o ni eyi jẹ atọka pe ajọ aṣọbode ilẹ wa ṣetan lati daboobo ilẹ wa lọwọ awọn to n lo ohun ija oloro lọna ti ko bofin mu.

Read Also: Àrùn Kọ́lẹ́rà tàn dé ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́ta ló ti pa

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni ajọ aṣọbode ilẹ wa ri ohun ija oloro yii gba lẹnu ibode Onne Port, to wa nipinlẹ Rivers, ti ọwọ wọn si tẹ awọn afurasi mẹta pẹlu, to jẹ pe wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọlọwọ. Biliọnu mẹtala ataabọ Naira, ni wọn ni wọn san lẹnu ibode fun awọn ohun ija ti wọn fẹẹ ko wọle yii.

    Kokumọ ni awọn ti gbẹsẹ le awọn ohun ija yi, awọn yoo si ba a jẹ ni ilana ti ofin lakalẹ. O waa gboṣuba fun ajọ aṣọbode ilẹ wa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe yii, to si gboṣuba fun oudamọran pataki si aarẹ lori eto aabo, Mallam Nuhu Ribadu, fun atilẹyin nla to n ṣe fun ajọ naa.

More posts