Se ẹni ti yoo ba pẹgan ajanaku ni yoo sọ wipe mo ri nkan fiiri, ti a ba ri erin a o sọ wipe a ri erin. Ni ọsẹ to kọja ni ilumọka ọjọgbọn onimọ ninu litiresọ nni Wọle Soyinka pe ọmọ aadọrun ọdun (90) loke eepẹ. Ọjọbi to lapẹrẹ yii ni gbogbo awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye ba se lati ba ọjọgbọn yii dupẹ lọwọ adaniwaye fun ore ọfẹ to fun un.
Ni nkan bi ọdun diẹ sẹyin nigbati mo jẹ akọroyin nilu llọrin ni mo ni anfani lati pade adajọ agba nni Kayọde Ẹsọ ẹni to mọ apade ati alude isẹ ofin to tun ni anfani lati da ẹjọ ọjọgbọn Soyinka ti wọn gbe wa siwaju rẹ ni asiko rogbodiyan to waye nipinlẹ iwọ oorun lẹyin isẹiẹ kayefi nni ti wọn sọ di ‘operation wẹt ẹ’
Adajọ Ẹsọ sọ fun mi pe bi o tilẹ jẹ wipe isẹlẹ ti mo beere lọwọ rẹ ti le ni ogoji ọdun sugbọn se lo dabi ana loju oun ati pe ibeere mi lori rẹ mu ki oun ranti ọjọ ati bi awọn alagbara nijọba fẹ fi dandan ran Soyinka lẹwọn ọsangangan boya o jẹbi tabi ko jẹbi. Sugbọn ti ọlọrun fun oun ni ọgbọn ati oye lati gbena woju ẹkun ijọba lati se ohun to tọ to si di ohun a pe tọka si titi di akoko yii
Adajọ Ẹsọ sọ wipe bi oun se jẹ ọkan ninu ọdọmọde adajọ nigba naa, iriri oun ati awọn irin ajo ti oun ti rin ninu isẹ ofin ti ko lafiwe lakoko naa lo fun oun ni igboya lati dajọ ododo gẹgẹbi ẹjọ ti onikaluku ro nile ẹjọ lai bikita ohun ti ijọba igba naa fẹ. O fikun ọrọ rẹ wipe isẹlẹ manigbagbe ni ẹjọ naa jẹ titi di oni. Eyi lo mu ki ogbontarigi adajọ yii pe akọle ọkan ninu awọn iwe to kọ lati fi peri isẹlẹ manigbagbe yii ni “The Mystery Gunman”
Ẹni kẹni to ba ka iwe yii yoo mọ iru ẹni ti Soyinka jẹ ati iru irin ajo to ti rin yala gẹgẹbi olukọ Yunifasiti ni,ajijagbara, olukọtan, adari ere ori itage, osere ati ọjọgbọn to gbe ounjẹ fẹgbẹ to tun gbawo bọ.
Ṣe ti ọmọde ko ba ba itan, o yẹ ko ba arọba, arọba si ree baba itan ni. Ninu iwe yii ni Adajọ Ẹṣọ to da ẹjọ to le koko bii oju ẹja titi di oni yii, to si jẹ ohun a ri tọka si, sọ diẹ nipa ọmọ bibi ilu Abẹokuta ati ljẹbu, tabi ki a kuku pe e ni ljẹgba.
Ṣe ọrọ lo ṣebi ọrọ ni ipinlẹ Iwọ-Oorun lọjọsi (Western region) ti ẹyẹ ko ke bii ẹyẹ, ti ọmọ eeyan ko fọhun bii ọmọ eeyan, ti ruke-rudo ṣẹlẹ nipa ọrọ oṣelu eyi to sọ ipinlẹ naa di oju ogun, asiko yii ni gomina igba naa, Ladoke Akintọla, fẹẹ ba gbogbo awọn eeyan ipinlẹ naa sọrọ pe ki wọn sinmi agbaja atipe oorun to wa loke nigba naa to aṣọ ipinlẹ naa lati gbẹ.
Akoko yii ni alujannu kan yọ si ileeṣẹ tẹlifisan ipinlẹ naa to wa l’Agodi, niluu lbadan, pẹlu ibọn ilewọ, ko beṣu, ko bẹgba, o kọri si ibi apoti igbohun safẹfẹ ileeṣẹ tẹlifisan yii, to si yọ ibọn si arakunrin kan ti wọn n pe ni Akinwale Ọṣin, ẹni to jẹ alakooso awọn oniroyin lakoko yii pe kó kó téèpù agbọrọsọ ti wọn ti fi ka ohùn pirẹmia ipinlẹ naa silẹ foun, ko si gba eyi ti yoo fi dipo rẹ lọwọ oun pẹlu aṣẹ pe ko tẹ ẹ bọ ẹrọ amohun bu gbamu ki gbogbo ipinlẹ naa le gbọ ọ.
Ninu iwe rẹ ni Ẹṣọ ti sọ pe “Gbogbo ẹri to wa nile-ẹjọ yii lo tako ara wọn, to si fi han pe Akinwale Ọṣin, kọkọ sọ pe oun o mọ ẹni to yọ ibọn soun lati gba teepu Pirẹmia ati pe ọkunrin naa ko lo iboju, ṣugbọn nigba to ya, o ni oun mọ ẹni naa ati pe Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ni, bẹẹ si ni olupẹjọ ijọba ko fidi rẹ mulẹ daadaa pe Wọle Ṣoyinka lo ṣe ohun ti wọn lo ṣe yii.”
Bo tilẹ jẹ pe gbogbo ọna ni ijọba Ladoke Akintọla san lati ri pe wọn ran Ọjọgbọn yii ni ẹwọn gbere, ṣugbọn ori ko o yọ lati ri adajọ to ni ipinnu lati ṣe ohun to tọ yatọ si ohun ti ijọba n fẹ ko ṣe.Ni ipari atotonu, Adajọ Ẹṣọ ṣi agbada lori eṣu, o fi ye ijọba pe ofin ki i bẹru atipe ofin ni olugbeja ẹni ti ko leeyan. “Pẹlu gbogbo ṣegeṣege ẹlẹrii ati aifidi ẹjọ rẹ mulẹ to latọwọ olupejọ ijọba pe Wọle Ṣoyinka ṣe ohun ti wọn lo ṣe yii, o da mi loju pe ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, mo da a silẹ ko ma a lọ layọ ati alaafia.”
Nigba ti Ọjọgbọn yii pe ẹni ọgọrin ọdun loke eepẹ, Yunifasiti lbadan, ibi ti ogunna gbongbo olukọ yii ti bẹrẹ ipilẹṣẹ irinajo rẹ, fi apejẹ nla da a lọla. Nibi apejẹ yii ni wọn ti ṣi àwọ̀n gbòòrò to boju ẹni ti wọn n pe ni Burọda Kongi, Kaako onikumọ ẹkun ati Olohun-iyọ.
Ninu ọrọ apilẹkọ ti wọn fi yẹ Ọjọgbọn yii si ni wọn ti fi we ọti oyinbo to wa ninu ọpalaba fun ọdun pipẹ, bo ṣe n dara si , bẹẹ lo n dun si. Ṣe Yoruba bọ, wọn ni ti a ba peri akọni, o di dandan ka fida lalẹ gaa-ra-ga.“Ko si ẹnikẹni ni Naijiria lonii to lami-laaka bii rẹ ninu irin ajo rẹ ninu ẹkọ literaṣọ, ere ori itage, iwe kikọ yala ni ilana ewi tabi ọrọ geere. Ko si ijọba ti ko bẹru rẹ, bẹẹ lo jẹ ajijagbara to di eegun aja sọrun ijọba ologun ni Naijiria.
“Nipasẹ gbogbo akitiyan ki i gbọ, ki i gba to yan laayo, o lo ọdun meji, oṣu mẹrin ati ọjọ mejilelogun lọgba ẹwọn. Ni kete to tun jade lo pada si iwa akin rẹ, ọmọ Ṣoyinka gbona bii ẹlẹgun Ṣango, o le bii apaadi, ṣe ajanaku kọja mo ri nnkan firi, ti a ba ri erin ka sọ pe a ri erin. Akọni onkọwe ni, oludari ere itage ni, olukọ tiru rẹ ko pe meji ni, o gbọn bii aṣahun, o fiwa jọ kinniun ibẹru, ẹni ògún, ẹni ògùn, ẹni oògùn, o mu lẹnu bii agogo bẹẹ lo logba bii elewi odo.”
Ti a ba pe e ni akọni, a ko jayo pa, ti a ba pe e ni ọjọgbọn ninu imọ ede gẹẹsi, oju ọna la wa, ti a ba si pe e ni ajijagbara, deede lo ṣe, a ba a si pe e ni olukọ to gbounjẹ fẹgbẹ to gbawo bọ, a ko ṣi wi . Bẹẹ, ti a ba si pe e ni o dami oke ru todo, a ko jayo pa, to ba si buṣe gada, to buṣe gege ti a pe e ni oṣere ori itage, oju ọna la wa, ti oju ba po firi, to dijo kole kole, ti a ba pe e ni oludasilẹ ẹgbẹ òkùnkùn, a ko bọmọ jẹ.
Tabi ka kuku da a silẹ, ka tun un sa, ka pe e ni ọkan ninu awọn ogboju ọdẹ ninu igbo irunmọlẹ, deede ni.Ṣugbọn ohun to daju ṣaka ni pe Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka to gun akasọ aadọrun ọdun loke eepẹ kii ṣe ẹran rirọ rara. Ẹ mu un, ẹ ki i, ẹran bii òòrẹ̀ kọ. Ṣe Yoruba bọ wọn ni ju u si mi , ju u si ọ, ki i ṣe bii ti odi ẹyin. Ọga lokete ninu ẹranko ti i ko ebu ninu igbo, ti ere ba di ere ka dori kodo, ko si ẹyẹ ti yoo ṣe bii adan ninu oko.
Read Also: For Wole Soyinka @ 90
Yoruba bọ, wọn ni ti a ba peri akọni, o di dandan ka fida lalẹ gaa-ra-ga.“Ko si ẹnikẹni ni Naijiria lonii to lami-laaka bii rẹ ninu irin ajo rẹ ninu ẹkọ literaṣọ, ere ori itage, iwe kikọ yala ni ilana ewi tabi ọrọ geere. Ko si ijọba ti ko bẹru rẹ, bẹẹ lo jẹ ajijagbara to di eegun aja sọrun ijọba ologun ni Naijiria.
“Nipasẹ gbogbo akitiyan ki i gbọ, ki i gba to yan laayo, o lo ọdun meji, oṣu mẹrin ati ọjọ mejilelogun lọgba ẹwọn. Ni kete to tun jade lo pada si iwa akin rẹ, ọmọ Ṣoyinka gbona bii ẹlẹgun Ṣango, o le bii apaadi, ṣe ajanaku kọja mo ri nnkan firi, ti a ba ri erin ka sọ pe a ri erin. Akọni onkọwe ni, oludari ere itage ni, olukọ tiru rẹ ko pe meji ni, o gbọn bii aṣahun, o fiwa jọ kinniun ibẹru, ẹni ògún, ẹni ògùn, ẹni oògùn, o mu lẹnu bii agogo bẹẹ lo logba bii elewi odo.
Wọlé ọmọ sóyínká
Ẹja tí ń dabú rú
Kò ju pọ́lọ́rọ́ lọ
Ìtàkùn tí kọ erin lẹ́sẹ́
Tí lákátabú fi dèrò ilẹ̀
Kò ju yánwọ́nrán lọ
Dídá la dá ẹwà mọ́ ọ̀kín
Elédùà ló se tolóòlà ijù bẹ́ ẹ̀
Tó bí ẹgbẹ̀rún akin lọmọ
Ní kékeré lọmọ egbin ti dára
Kékeré lọmọ òjòlá
Ti fi gígùn sayọ̀
llé ló bá akíkanjú
Tí mo bá rántí
Ìjà àwọn obìnrin ẹ̀gbá ní’jọ́sí
Mo rántí yeye tó bí ọ lọ́mọ
Egun ẹran tíí dàmú èrìkì
Ní pínnísín ló ti mú wà akin
Ni màjèsín ló ti n hùwà àgbà
Èdùnmàrè ló dirí ẹwà fákùkọ
O dàgbà ọ̀jẹ̀ tí fẹ̀kú se fújà
O di jáwọn láyà baba ìjayà
Níbi wọ́n gbé ń dáná irọ́
Àpáta le, olóko da sí
O di ẹgẹrẹmìtì ìgànná
Tí wó lu asebi
Láìì mọ́kọ́ dání
Láìì so àdá mọ́ tòbí
O dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ nígbàlẹ̀ ìkà
O músẹ́ ọpọlọ wu ni se
O dàgbà òpìtàn
Nígbàlẹ̀ àwọn ọlọ́pọlọ
Bí ayé bá ń jẹ́ ayé
Tí ìgbà bá n jẹ́ ìgbà
lpa abẹ́rẹ́ lokún ń tọ̀
Ìran tó ń bọ̀
Kò ní gbàgbé rẹ
Wọlé ọmọ Sóyínká
